Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:7
33 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a, akọ àti abo ni Ó dá wọn.


Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀.


Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”


Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá.


Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú.


(Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi, àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.)


Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi, àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè.


Kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú.


Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.


Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀.


Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.


Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.


Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà, tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.


Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀


Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́, èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀. Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?


Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.


Ẹni ààmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.


Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí: Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè.


Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, èmi yóò sì fi awọ ara bò yín: Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”


Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ Olúwa fún Israẹli ni. Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀:


Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?”


“Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí


Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́!


Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.


Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ”


Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a;” Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè.


Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.


Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.


Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.


Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa.


Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan