Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ́ ti OLUWA Ọlọrun dá aiye on ọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:4
27 Iomraidhean Croise  

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.


Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.”


Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà.


Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà.


Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn.


Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.


Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Arfakṣadi.


Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.


Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un.


Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki.


Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.


Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri.


Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.


Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “Olúwa, òun ni Ọlọ́run! Olúwa, òun ni Ọlọ́run!”


O sì wí pé: “Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.


Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?


“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.


Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa? Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?


Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.


Ológun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,


Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Lefi lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.


“Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun: Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.


Johanu, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia: Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;


“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”


wí pé: “Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀, ìwọ sì ti jẹ ọba.


Mo sì gbọ́ angẹli ti omi wí pé: “Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan