Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 13:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 13:4
21 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.


Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.


Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi. Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.


Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.


Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.


Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,


Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa


Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.


Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.


Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.


Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.


Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,


Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.


“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa, láti fi ọkàn kan sìn ín.


Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan