Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:7
15 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.


Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.


Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.


Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.


Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.


Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.


Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.


Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.


Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.


Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run; Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.


Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́; wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.


Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.


Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan