Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:6
23 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún ààmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún,


Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.”


Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.


Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.


Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?


Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní


Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.


Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀ Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.


Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run; Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.


Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́; wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.


Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.


Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.


Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.


Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata. Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.


Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.


“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀, o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.


Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ Olúwa fún Israẹli ni. Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀:


Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan