Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:4
10 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára.


Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára.


láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.


Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.


Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà.


Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni yóò máa yìn ọ́ Olúwa; àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.


Olúwa dára sí ẹni gbogbo; ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.


Ìmọ́lẹ̀ dùn; Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.


Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.


Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan