Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:2
17 Iomraidhean Croise  

Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”


Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú, ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.


Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀,


Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.


Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ, ni a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.


Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.


Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.


Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú Òkun


Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.


Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;


Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu, Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”


Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí— ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀— Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.


Mo bojú wo ayé, ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo àti ní ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí.


Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.


Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.


Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń rábàbà sórí ọmọ rẹ̀, tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan