Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 4:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Mo láyọ̀ pupọ ninu Oluwa nítorí ọ̀rọ̀ mi tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọjí ninu èrò yín. Kò sí ìgbà kan tí ẹ kì í ronú nípa mi ṣugbọn ẹ kò rí ààyè láti ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ṣugbọn emi yọ̀ gidigidi ninu Oluwa pe, asiwá-asibọ̀ ero nyin tun sọji fun mi, eyiti ẹ ti nro nitotọ, ṣugbọn ẹnyin kò ni akokò ti o wọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 4:10
11 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.


Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́, pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?


Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.


Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.


Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì.


Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.


Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni.


Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi. Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.


Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín:


Nítorí iṣẹ́ Kristi ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan