Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 3:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Mo ka gbogbo nǹkan wọnyi sí àdánù nítorí ohun tí ó ṣe iyebíye jùlọ, èyí ni láti mọ Kristi Jesu Oluwa mi, nítorí ẹni tí mo fi pàdánù ohun gbogbo, tí mo fi kà wọ́n sí ìgbẹ́, kí n lè jèrè Jesu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 3:8
53 Iomraidhean Croise  

“ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jeroboamu. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jeroboamu, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Israẹli. Èmi yóò mú ilé Jeroboamu kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán.


Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jesebeli ni èyí.’ ”


Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’


Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.


Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.


Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.


“Nítorí tiyín èmí yóò ba àwọn ọmọ yín wí, èmi ó sì fi ìgbẹ́ rẹ́ yín lójú, àní àwọn ìgbẹ́ ọrẹ ọwọ́ yín wọ̀nyí, a ó sì kó yín lọ pẹ̀lú rẹ̀.


Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra nípa ìgbọ́wọ́sókè láti fi ṣe ibùgbé yín, bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne àti Joṣua ọmọ Nuni.


Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?


Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.


Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.


Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”


Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.


Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán.


Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.


Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?” Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”


Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”


Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.


Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn.


tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.


Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú.


Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè.


Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.


Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.


Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìhìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,


Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.


Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi. Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.


Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀;


Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá.


Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi.


Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé.


Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin;


Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”


Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.


Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀.


Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.


Ṣùgbọ́n ẹ máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. Ẹni tí ògo wà fún nísinsin yìí àti títí láé! Àmín.


Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi.


Wọ́n ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró: ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa.


Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan