Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 3:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ní ti ìtara ninu ẹ̀sìn, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Kristi. Ní ti òdodo nípa iṣẹ́ Òfin, n kò kùnà níbìkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 3:6
25 Iomraidhean Croise  

Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn: Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda.


Jehu wí pé, “Wá pẹ̀lú mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.


Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?


Bí ẹran-ara rẹ̀ bá yípadà sí funfun, kí o farahan àlùfáà.


“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo.


Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.


Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.


Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin.


àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Damasku láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerusalẹmu, láti jẹ wọ́n ní yà.


Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi.


Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.


Èmi sì ti wà láààyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú.


Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run.


Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn aposteli, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní aposteli, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run.


Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé.


Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́;


Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn: ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́.


Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan