Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 3:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní gbolohun kan, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa. Kò ṣòro fún mi láti kọ àwọn nǹkankan náà si yín, ó tilẹ̀ dára bẹ́ẹ̀ fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LI akotan, ará, ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa. Kì iṣe inira fun mi lati kọwe ohun kanna si nyin, ṣugbọn fun nyin o jẹ ailewu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 3:1
46 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro.


Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.


Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà. Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi ààmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà.


Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ Olúwa ni agbára yín.”


Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.


Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn.


Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo; ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.


Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.


Ṣe inú dídùn sí Olúwa; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.


Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi: èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.


Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. Tan ààbò rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.


Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn


Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.


Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.


Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè láti inú ìrora ọkàn yín àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.


Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.


Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.


Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”


Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.


Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.


Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.


Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.


Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.


Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀.


Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àwọn ọmọ Lefi láti ìlú u yín: kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín.


Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin, àwọn ẹrú yín ọkùnrin àti àwọn ẹrú yín obìnrin, àwọn Lefi tí ó wà ní ìlú yín, àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárín yín.


Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara.


Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.


Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.


Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe. Nísinsin yìí, a béèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jesu Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí.


Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo


Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀;


Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀


Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.


Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí;


Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan