Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:12
10 Iomraidhean Croise  

Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un.


Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni Olúwa wí.


Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.


Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.


Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.


Bí arákùnrin tìrẹ gan an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn, (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀


Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.


Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan