Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:10
14 Iomraidhean Croise  

Ọba sì pàṣẹ fún Joabu àti Abiṣai àti Ittai pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Absalomu.


Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.


Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà.


Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́.


Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbàárùn-ún olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìhìnrere.


Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèkéé, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kristi nínú yín.


Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.


Sí Timotiu ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa wa.


Sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kristi Jesu Olùgbàlà wa.


Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.


Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere


Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan