Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:9
28 Iomraidhean Croise  

Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé Olúwa ní ọwọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn ní ọwọ́.”


Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì.


Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú.


Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.


Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa: nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.


Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.


Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.


Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,


Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀. Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.


Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ.


“ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.


Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.


Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.


“Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.


Háà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.


Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan