Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Háà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:8
15 Iomraidhean Croise  

nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.”


Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’.


Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.


Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.


Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.


Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu.


Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?


“Olóòtítọ́ ni Olúwa, ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn; ẹ wò mí wò ìyà mi. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.


“Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.


Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.


Nígbà tí mo bá sì ti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tan, Èmi yóò sì rántí, ojú yóò tì ọ́, ìwọ kò sì ní le ya ẹnu rẹ mọ́ nítorí ìtìjú rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”


Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́.


Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan