Daniẹli 9:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ. Faic an caibideilYoruba Bible7 Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ. Faic an caibideil |