Daniẹli 9:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní5 Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀. Faic an caibideilYoruba Bible5 “A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ5 Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ: Faic an caibideil |
Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn.