Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gebrieli ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣálẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Bí mo ti ń gbadura, ni Geburẹli, tí mo rí lójúran ní àkọ́kọ́ bá yára fò wá sọ́dọ̀ mi, ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:21
27 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọtẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì ṣí ìdáhùn, kò sì ṣí ẹni tí ó kà á sí.


Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.


Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́


Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ, Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.


Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.


Ọ̀dọ́-Àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rú ẹbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́-àgùntàn èkejì ní àṣálẹ́.


Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò.


Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn.


Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá.


bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Noa, Daniẹli àti Jobu tilẹ̀ wà nínú rẹ, kìkì ẹ̀mí ara wọn nìkan ni wọ́n lé fi òdodo wọn gbàlà, Olúwa Olódùmarè wí.


Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi.


Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun.


Ẹ̀wẹ̀, ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní agbára.


Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gebrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”


Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.


Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”


Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá.


Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti,


Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”


Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:


Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.


Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.


Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?


Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé; “Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”


Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti tí sulfuru: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan