Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Gbogbo Israẹli ti rú òfin rẹ, wọ́n ti pada lẹ́yìn rẹ, wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́ tìrẹ. Nítorí náà, ègún ati ìbúra tí Mose, iranṣẹ rẹ kọ sinu ìwé òfin ti ṣẹ mọ́ wa lára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:11
30 Iomraidhean Croise  

Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.


‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Juda ti kà.


Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”


Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún àti Israẹli fún ẹ̀gàn.


Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́.


“Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí? Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,” ni Olúwa wí.


Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ, wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ, mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà, nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.


Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.


Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀.


Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí.


Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.”


Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èso ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.


Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”


Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mose bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, síbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ rẹ.


Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.


Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín? “Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”


Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.


Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”


Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan