Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Susa ní agbègbè ìjọba Elamu: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Ulai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:2
24 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.


Ní àsìkò yìí ni Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu àti Tidali ọba Goyimu


Ọ̀rọ̀ Nehemiah ọmọ Hakaliah: Ní oṣù Kisleu ní ogún ọdún (ìjọba Ahaswerusi ọba Persia) nígbà tí mo wà ní ààfin Susa,


Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa,


Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Susa, sí abẹ́ ìtọ́jú Hegai. A sì mú Esteri náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hegai lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin.


Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.


Esteri sọ wí pé, “Alátakò àti ọ̀tá náà ni Hamani aláìníláárí yìí.” Nígbà náà ni Hamani wárìrì níwájú ọba àti ayaba.


Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.


Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba.


Àwọn Júù tí ó wà ní Susa sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Susa, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.


Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti Òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.


Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù. Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn! Èmi yóò mú gbogbo Ìpayínkeke dópin, ni ó búra.


Gbogbo àwọn ọba Simri, Elamu àti Media.


Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.


“Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.


Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù àkọ́kọ́, bí mo ti dúró sí etí i bèbè odò ńlá Tigirisi,


“Ọkàn èmi Daniẹli, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.


Daniẹli sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi Òkun ńlá sókè.


Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.


Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, àwọn ìwo náà sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.


Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi: “Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran, Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.


Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,


Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti tí sulfuru: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan