Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 A fún un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojoojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 A fi ogun náà ati ẹbọ sísun ojoojumọ lé e lọ́wọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, a sì já òtítọ́ lulẹ̀. Gbogbo ohun tí ìwo náà ń ṣe, ni ó ṣe ní àṣeyọrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 A si fi ogun le e lọwọ pẹlu ẹbọ ojojumọ nitori irekọja, o si ja otitọ lulẹ, o si nṣe eyi, o si nri rere.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:12
14 Iomraidhean Croise  

Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.


Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀.


Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ


Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.


Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn, àti ti òdodo dúró lókèèrè; òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà, òdodo kò sì le è wọlé.


Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?


Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnrarẹ̀.


Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn,


Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, sí àríwá, àti sí gúúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó le è dojúkọ ọ́, kò sí ẹnìkan tí ó le è yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.


A sì fún un láti máa bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀.


Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín-yìí!”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan