Daniẹli 7:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 “Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná. Faic an caibideilYoruba Bible9 “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́. Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀, aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun, ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná, kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná. Faic an caibideilBibeli Mimọ9 Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná. Faic an caibideil |
Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà ààmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún ọdún.