Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 “Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:6
10 Iomraidhean Croise  

Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi Kedari tó ga jùlọ,


Nígbà náà, ni ó wí pé, “Ṣé o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Láìpẹ́ èmi yóò yípadà lọ bá àwọn ọmọ-aládé Persia jà, nígbà tí mo bá lọ àwọn ọmọ-aládé Giriki yóò wá;


“Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jẹ ọba lórí i gbogbo ayé.


“Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.


“Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’


Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún Èmi yóò fi ara pamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.


Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí beari ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún: dragoni náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan