Daniẹli 6:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún. Faic an caibideilYoruba Bible7 gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Gbogbo awọn olori alakoso ijọba, awọn bãlẹ ati awọn arẹ bãlẹ, awọn ìgbimọ, ati olori ogun jọ gbìmọ pọ̀ lati fi ofin ọba kan lelẹ, ati lati paṣẹ lile kan, pe ẹnikẹni ti o ba bère nkan lọwọ Ọlọrun tabi eniakenia niwọn ọgbọ̀n ọjọ bikoṣepe lọwọ rẹ, ọba, a o gbé e sọ sinu ihò kiniun. Faic an caibideil |