Daniẹli 6:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara. Faic an caibideilYoruba Bible4 Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ4 Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. Faic an caibideil |