Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan lára ìgbèkùn Juda, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí. Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:13
9 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀.


Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah.


Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”


àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.


Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”


Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda.


Nígbà náà ni a mú Daniẹli wá síwájú ọba, ọba sì sọ fún un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan lára àwọn tí baba mi mú ní ìgbèkùn láti Juda!


Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.”


Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan