Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nígbà náà ni, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí Daniẹli tí ó ń gba àdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Àwọn ọkunrin wọnyi bá kó ara wọn jọ. Wọ́n wá wo Daniẹli níbi tí ó ti ń gbadura, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi rìn wọle, nwọn si ri Danieli ngbadura, o si mbẹbẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:11
7 Iomraidhean Croise  

bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ;


Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.


Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ.


Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.


Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró: Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”


Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé: “Ìwọ Dariusi ọba, kí o pẹ́!


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan