Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nigbati Danieli si ti mọ̀ pe a kọ iwe na tan, o wọ ile rẹ̀ lọ; (a si ṣi oju ferese yara rẹ̀ silẹ siha Jerusalemu) o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ nigba mẹta lõjọ, o gbadura, o si dupẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi on ti iṣe nigba atijọ ri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:10
47 Iomraidhean Croise  

Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì.


nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí,


“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ,


Nígbà tí Solomoni ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run


Solomoni ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárín àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run.


Tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ;


Ní ìgbà tí ó di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi.


Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sálọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sálọ sínú tẹmpili láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!”


Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.


Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀, èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀; ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.


Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi.


Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.


Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín, Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa;


Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan lára ìgbèkùn Juda, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí. Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.”


Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé: “Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.


Nígbà náà ni mo wí pé, ‘a ta mí nù kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’


Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”


“Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.


Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà.


Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:


Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí.


Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.


Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà.


Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà.


Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.


Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.


Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”


Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!


Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.


Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó.


Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi.


Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.


Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú.


Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.


Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.


Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.


Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.


Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan