Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nígbà náà ni Belṣassari ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú sí i. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè Belṣassari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nigbana ni ẹ̀ru nla ba Belṣassari ọba gidigidi, oju rẹ̀ si yipada lori rẹ̀, ẹ̀ru si ba awọn ijoye rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:9
12 Iomraidhean Croise  

Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.


Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.


Béèrè kí o sì rí: Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?


Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí obìnrin tí ń rọbí.


Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku okun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́.


Ní ọdún kejì ìjọba Nebukadnessari, ó lá àlá, èyí tí ó mú kí ọkàn an rẹ̀ dàrú, kò sì le è sùn.


Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.


Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀


Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan