Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí fìtílà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ enia kan jade wá, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa-fitila li ãfin ọba: ọba si ri ọwọ ti o kọwe na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:5
15 Iomraidhean Croise  

pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?


Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.


Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.


Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.


Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.


A ti mú àwọn amòye àti àwọn awòràwọ̀ wá sí iwájú mí kí wọn ba à le è wá ka àkọsílẹ̀ yìí kí wọn sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ ohun tí ó jẹ́.


Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.


Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.


Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le è ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.


Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan