Daniẹli 5:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 Ọkùnrin náà ni Daniẹli ẹni tí ọba ń pè ní Belṣassari, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá da ojú rú, ránṣẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.” Faic an caibideilYoruba Bible12 nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.” Faic an caibideilBibeli Mimọ12 Niwọnbi ẹmi titayọ ati ìmọ, ati oye itumọ alá, oye ati já alọ́, ati lati ma ṣe itumọ ọ̀rọ ti o diju, gbogbo wọnyi li a ri lara Danieli na, ẹniti ọba fi orukọ Belteṣassari fun, njẹ nisisiyi jẹ ki a pè Danieli wá, on o si fi itumọ rẹ̀ hàn. Faic an caibideil |
Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.” Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ: