Daniẹli 4:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní5 Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí. Faic an caibideilYoruba Bible5 Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi. Faic an caibideilBibeli Mimọ5 Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi. Faic an caibideil |
Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.” Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ: