Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:32 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 A ó lé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárín àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

32 A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:32
22 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.


“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.


Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà? Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?


Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.


Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.


Farao wí pé, “Ni ọ̀la.” Mose sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa.


Nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.


Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.


Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”


Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa; a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n; ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.


Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí; gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò tí kò tó ohun tí kò sí.


Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.


Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.


Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.


Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.


A lé e kúrò láàrín ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko; ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù; ìrì ọ̀run ṣì sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.


Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan