Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:27 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

27 Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

27 Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

27 Nitorina ọba, jẹ ki ìmọran mi ki o jẹ itẹwọgba lọdọ rẹ, ki o si fi ododo ja ẹ̀ṣẹ rẹ kuro, ati aiṣedẽde rẹ nipa fifi ãnu hàn fun awọn talaka; bi yio le mu alafia rẹ pẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:27
44 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”


“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀.”


Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí,


Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.


Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.


Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.


Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, Mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.


Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’


“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’


Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”


Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́. Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ; yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà.


Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò.


Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”


Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa. “ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,”


Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín?


Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”


Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”


Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà, yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”


Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu. Ó sì sọ fun ara rẹ̀ pé, “Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.” Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́, ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.


Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.


Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.


Bí Paulu sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Feliksi, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsin yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”


Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà.


Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́.


Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú.


Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín.


Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,


Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.


Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.


Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.


nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá, kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni; kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”


Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.”


Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan