Daniẹli 4:23 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní23 “Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrín ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’ Faic an caibideilYoruba Bible23 Olùṣọ́, Ẹni Mímọ́ tí ọba rí tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, tí ó ń wí pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀ kí o sì pa á run, ṣugbọn kí ó ku kùkùté ati gbòǹgbò rẹ̀ ninu ilẹ̀, kí ó wà ninu ìdè irin ati ti idẹ, ninu pápá oko tútù, kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ káàkiri fún ọdún meje.’ Faic an caibideilBibeli Mimọ23 Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀, Faic an caibideil |