Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 “Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:22
18 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”


Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.


Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu.


Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odedi wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Samaria. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí Olúwa, Ọlọ́run baba yín bínú sí Juda ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run.


Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀


Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run, òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.


Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.


Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi Kedari tó ga jùlọ,


Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.


Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.


Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èso rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko igbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn.


Lẹ́yìn oṣù kejìlá, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Babeli,


Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ.


nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.”


Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan