Daniẹli 4:17 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní17 “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’ Faic an caibideilYoruba Bible17 Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’ Faic an caibideilBibeli Mimọ17 Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀. Faic an caibideil |