Daniẹli 4:14 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní14 ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. Faic an caibideilYoruba Bible14 ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ14 O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀: Faic an caibideil |
“Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrín ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’