Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:12
13 Iomraidhean Croise  

Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé, A sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.


“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.


Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.


Ẹni ààmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.


Ní ibi gíga òkè Israẹli ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso, yóò wa di igi Kedari tí ó lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀


Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.


ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrín èso rẹ̀, síbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé.”


“Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan.


Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”


Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan