Daniẹli 4:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Nebukadnessari ọba, Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé: Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! Faic an caibideilYoruba Bible1 Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé: “Kí alaafia wà pẹlu yín! Faic an caibideilBibeli Mimọ1 NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin. Faic an caibideil |
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnrarẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.
Lẹ́sẹ̀kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù Sifani. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Mordekai sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóso baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tà-dínláàádóje tí ó lọ láti India títí ó fi dé Kuṣi. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn.