Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:24 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Nígbà náà ni ó ya Nebukadnessari ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?” Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

24 Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

24 Nigbana ni Nebukadnessari ọba warìri o si dide duro lọgan, o dahùn, o si wi fun awọn ìgbimọ rẹ̀ pe, awọn ọkunrin mẹta kọ a gbé sọ si ãrin iná ni didè? Nwọn si dahùn wi fun ọba pe, Lõtọ ni ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:24
18 Iomraidhean Croise  

Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀.


Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.


Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.


Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”


Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.


Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”


“Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá.


Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.


Ọlọ́run mi rán angẹli i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pa mí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.”


Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún.


Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn.


Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò.


Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”


Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe? Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”


Bí Saulu sì ti wo Dafidi bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Filistini, ó wí fún Abneri, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Abneri, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Abneri dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan