Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:17 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

17 Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:17
34 Iomraidhean Croise  

Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai), máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù.


Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.”


Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i? Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;


Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ


Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.


Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú


Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.


Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.


Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”


Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀ ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun Ìpayà la ó mú kúrò pátápátá; kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.


Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.


Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí.


“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”


Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!” Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná.


Gbogbo àwọn ènìyàn ayé ni a kà sí asán. Ó ń ṣe bí ó ti wù ú, pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run, àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́ tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”


Nígbà náà, ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì mú Daniẹli, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún. Ọba sì sọ fún Daniẹli pé, “Kí Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn nígbà gbogbo kí ó gbà ọ́!”


Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Daniẹli jáde wá láti inú ihò. Nígbà tí a mú Daniẹli jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.


Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.”


Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa, Èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.


Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”


Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.


Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.”


Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?


Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀,


Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.


Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”


Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan