Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nebukadnessari ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè ìjọba Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nebukadinesari fi kìkì wúrà yá ère kan tí ó ga ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 2.7). Ó gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè Babiloni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NEBUKADNESSARI ọba, si yá ere wura kan, eyi ti giga rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa: o si gbé e kalẹ ni pẹtẹlẹ Dura, ni igberiko Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:1
29 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọrọ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Israẹli, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Ejibiti wá.”


Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia.


Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.


Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.


Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn.


Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán,


Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”


Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín.


Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi, àti wúrà láti Upasi; èyí tí àwọn oníṣọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà.


Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”


Nígbà náà ni ọba gbé Daniẹli ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀. Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Babeli àti olórí gbogbo àwọn amòye Babeli.


Daniẹli béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbèríko Babeli ṣùgbọ́n Daniẹli fúnrarẹ̀ wà ní ààfin ọba.


Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.


Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli.


Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.


Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.


Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Baali.


Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, si ìparun ara wọn.


Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘di alààyè?’ Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’ Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà? Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká; kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”


“Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀.


Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.


Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí Olúwa Ọlọ́run yín.


Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan