Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:46 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

46 Nígbà náà, ni Nebukadnessari ọba dojúbolẹ̀ níwájú u Daniẹli ó sì fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọn kí ó mu ọrẹ àti òórùn tùràrí fún Daniẹli

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

46 Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

46 Nigbana ni Nebukadnessari, ọba, wolẹ o si doju rẹ̀ bolẹ, o si fi ori balẹ fun Danieli, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o ṣe ẹbọ-ọrẹ ati õrùn didùn fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:46
12 Iomraidhean Croise  

Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.


Ó sì ṣe bí Peteru ti ń wọlé, Korneliu pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un.


Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀:


Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi,


Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”


Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́.


Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run,


Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.


Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.


Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.


Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.


Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bà mí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan