Daniẹli 2:45 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní45 Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́. “Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.” Faic an caibideilYoruba Bible45 Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.” Faic an caibideilBibeli Mimọ45 Gẹgẹ bi iwọ si ti ri ti okuta na wá laisi ọwọ lati òke wá, ti o si fọ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wura wọnni tutu; Ọlọrun titobi ti fi hàn fun ọba, ohun ti mbọ wá ṣe lẹhin ọla: otitọ si li alá na, itumọ rẹ̀ si daju. Faic an caibideil |
“Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojú rẹ—ìnira tí ó ti wá sórí wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Asiria wá títí di òní.