Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:44 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

44 “Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

44 Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

44 Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:44
38 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un.


Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé.


A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ”


Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.


Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun; pátápátá ni yóò sì dahoro.


Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, ìránṣẹ́ mi Dafidi ni yóò jẹ́ Ọmọ-aládé wọn láéláé.


ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:


Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́.


Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.


Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ;


Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀.


Báwo ni ààmì rẹ̀ ti tóbi tó, Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni; ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.


Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé. Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran


“Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé: ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli. “Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè Ó sì wà títí ayé; Ìjọba rẹ̀ kò le è parun ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun


Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.”


Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn Ọ̀gá-ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’


Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ-aládé, síbẹ̀, a ó pa á run ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn.


Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.


Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”


Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi.


Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?”


Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀.


Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”


‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan