Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:40 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

40 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tókù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

40 Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

40 Ijọba kẹrin yio si le bi irin; gẹgẹ bi irin ti ifọ tũtu, ti si iṣẹgun ohun gbogbo: ati gẹgẹ bi irin na ti o fọ gbogbo wọnyi, bẹ̃ni yio si fọ tũtu ti yio si lọ̀ wọn kunna.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:40
12 Iomraidhean Croise  

Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.


“Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin irin láti àríwá tàbí idẹ?


àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀.


“Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jẹ ọba lórí i gbogbo ayé.


Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀.


“Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.


Yóò di alágbára, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀. Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tó ń ṣe. Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́.


Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi: ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.


Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú


Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Romu yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan