Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:32 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 Wúrà ni orí rẹ̀, àyà ati apá rẹ̀ jẹ́ fadaka, ikùn rẹ̀ títí dé itan sì jẹ́ idẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

32 Eyi ni ere na; ori rẹ̀ jẹ wura daradara, aiya ati apa rẹ̀ jẹ fadaka, inu ati ẹ̀gbẹ rẹ̀ jẹ idẹ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:32
11 Iomraidhean Croise  

ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!


Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa; ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí. Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.


àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀.


Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.


Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”


“Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.”


A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan