Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:27 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

27 Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

27 Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

27 Danieli si dahùn niwaju ọba, o si wipe, Aṣiri ti ọba mbère, awọn ọlọgbọ́n, awọn oṣó, awọn amoye, ati awọn alafọṣẹ, kò le fi hàn fun ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:27
12 Iomraidhean Croise  

Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”


Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un.


Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.


ta ni ó ba ààmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,


Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí tìrẹ ni, láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.


Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.


Nígbà náà ni ọba yára pe àwọn onídán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó àti àwọn awòràwọ̀; àwọn tó ní ìmọ̀ àti àṣírí i títúmọ̀ ìràwọ̀, ọba pè wọ́n kí wọn wá sọ àlá tí ó lá. Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n dúró níwájú ọba,


Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan