Daniẹli 12:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335). Faic an caibideilYoruba Bible12 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ12 Ibukún ni fun ẹniti o duro dè, ti o si de ẹgbẹrun, ati ọdurun le marundilogoji ọjọ nì. Faic an caibideil |
Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà ààmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún ọdún.